Homeyoruba

yoruba

Ijọba ti gbẹsẹ kuro lori ofin konilegbele ni Kwara

Dada Ajikanje Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe ko si ofin konilegbele mọ nipinlẹ ọhun, bẹrẹ lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejila, oṣu yii. Ọgbeni Rafiu Ajakaye, ẹni ti i ṣe akọwe gomina nipa eto iroyin lo fọwọ si ikede yii lori ikanni abẹyẹfo ijọba ipinlẹ ọhun. Bakan naa ni ikede ọhun sọ...

Aṣiri Ṣẹgun ti wọn lo pa ọrẹbinrin ẹ, to tun sin in sinu igbo ti tu o

Jide Alabi L’Ekoo, ọwọ ọlọpaa ti tẹ ọkunrin ọmọ ọdun méjìdínlógún kan, Ṣẹgun Titilayọ, lori ẹsun pe o pa ololufẹ ẹ, o si sin in lai sọ fẹnikẹni. Ọmọ ilu kan ti wọn n pe ni Otolu, nijọba ibilẹ Lẹkki, ni wọn pe ọkunrin yii, bẹẹ ni, ololufẹ ẹ ti wọn...

Inu otẹẹli lawọn SARS pa ọmọ mi si n’Iwoo, wọn tun ji miliọnu mẹrin naira rẹ lọ-Ayinla

Florence Babasola, Oṣogbo Barisita Fatai Ajani to jẹ agbẹjọro fun baba agba kan, Ayinla Rasheed, to tun n ṣoju fun ẹni to ni otẹẹli Ile Labọ Sinmi Oko, niluu Iwo, lo kọkọ fara han niwaju igbimọ tijọba ipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ lori wahala awọn ọlọpaa loni-in. Ninu iwe ẹsun ti ọkunrin...

Ọwọ ọlọpaa tẹ Lawrence to fipa ba abirun sun lẹyin mọṣalaaṣi l’Oṣogbo

Florence Babasola, Oṣogbo Ọmọkunrin kan, Akinọla Lawrence Adetayọ, ẹni ogoji ọdun, lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii lori ẹsun pe o fipa ba ọmọbinrin abirun kan lo pọ lọna to mu ifura dani. Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣe ṣalaye fun ALAROYE, aago meje...

Ijamba ọkọ gbẹmi eeyan kan ninu ijamba ọkọ nitosi Arakeji, l’Ọṣun

Ọkunrin kan niwadii ti fidi rẹ mulẹ bayii pe o gbẹmi mi ninu ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ niluu Olootu-Agbe, nitosi Ikeji Arakeji, nipinlẹ Ọṣun. Ni nnkan bii aago kan kọja iṣẹju mẹwaa ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, la gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. Ọkọ Toyota  Sienna kan to ni nọmba EKY...

 O ma ṣe o, tankan epo re sinu odo Soka, n’Ibadan, dẹrẹba to wa a ti jade laye

Ọlawale Ajao, Ibadan Awakọ tanka epo bẹtiroolu kan ti j’Ọlọrun nipe ninu ijanba ọkọ to waye lori biriiji Soka, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. Niṣe ni ọkọ nla ọhun gbokiti sinu omi Soka lati ori biriiji odo naa. Gẹgẹ b’awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣe sọ, ṣadeede lọkọ ọhun to n...

Idunnu ṣubu layọ ni Yunifasiti Eko, nigba ti Ọjọgbọn Ogundipẹ bẹrẹ iṣẹ pada

JIde Alabi Pẹlu idunnu lawọn oṣiṣẹ Yunifasiti Eko, UNILAG, fi ki Olori ileewe giga naa, Ọjọgbọn Ọlọruntoyin Ogundipẹ, kaabọ pada, lẹyin ti Aarẹ Buhari ti paṣe wi pe ko maa ba iṣẹ ẹ lọ. Bawọn oṣiṣẹ ileewe giga ọhun ti foju kan an lonijo ti n jo, ti awọn to le...

Korona ti pa Jerry Rawlings, olori ilẹ Ghana tẹlẹ

Olori ijọba ile Ghana tẹlẹ, Ọgagun Jerry Rawlings, ti ku o. Arun korona lo pa a loni-in yii gan-an, ọmọ ọdun mẹtalelaadọrin (73) si ni. Ohun to ya awọn eeyan lẹnu ni pe ko ti i ju oṣu kan lọ to ṣẹṣẹ sin oku iya rẹ, n loun naa...

Ija Nnamdi Azikiwe pẹlu ajọ FEDECO to nṣeto ibo lọdun 1979 (2)

Ohun ti ọrọ owo-ori awọn ti wọn fẹẹ du ipo aarẹ lasiko idibo ọdun 1979 yẹn da silẹ, nnkan rẹpẹtẹ ma ni o. Diẹ lo ku ki ọrọ naa da ọpọlọpọ eto ti wọn ti ṣe silẹ fun idibo ọhun ru pata. Nnamdi Azikiwe, baba to fẹẹ du ipo...

Tinubu loun faramọ bi Sanwoolu ṣe fagile owo ifẹyinti awọn gomina Eko

Aderounmu Kazeem Bi gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu, ṣe fopin si sisan owo oṣu fawọn gomina to ti kuro nipo l’Ekoo, Aṣiwaju Bọla Tinubu ti sọ pe igbesẹ to dara ni, bẹẹ lo dun mọ oun ninu daadaa. Tinubu, lori ikanni abẹyẹfo ẹ, sọ pe igbesẹ akin ni gomina naa gbe,...

Nitori SARS, wọn wọ Fẹmi Falana lọ sile-ẹjọ agbaye

Aderounmu Kazeem Ẹgbẹ kan ti wọn lawọn n fẹ daadaa fun Naijiria ti wọ Amofin agba nni, Fẹmi Falana, lọ sile-ẹjọ to n gbẹjọ iwa ọdaran lagbaye (ICC) lori ẹsun wi pe o n ṣatilẹyin fawọn ọdọ to ṣewọde tako SARS. Orukọ ẹgbẹ to kọwe afisun nipa Falana, sile ẹjọ agbaye...

Ẹ ba mi dupẹ, Sẹkinatu Abẹjẹ, ọmọ mi ti bimọ o

Ẹ wo o, nnkan ti waa bajẹ patapata. Ọrọ aye yii, ti mo ba ni ki n maa ro o, oluwa ẹ ko ni i ṣe nnkan meji mọ o. Ṣe ẹ mọ pe nigba kan, ilu oyinbo ni opin irin-ajo fun awọn ọmọ wa. Ti wọn ba ti lọ...

O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Fani-Kayọde paapaa ni alaye lati ṣe Bo ba ṣe pe Oloye Fani-Kayọde, ọkan ninu awọn oloṣelu ilẹ Yoruba to ti ṣe minisita nigba kan, ni oogun ti yoo lo to n jẹ bii idan ni, iba lo kinni naa ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja yii, lori ibo ti...

Awọn Ibo kọlu ọmọ wọn to gbe awọn olorin lọ si kootu nitori ọrọ SARS

Aderounmu Kazeem Lati ana Wẹsidee, Ọjọruu, ti iroyin ti gba igboro kan pe ọkunrin ajafẹtọọ-ọmọniyan, Kenechukwu Okeke, ti pe awọn eeyan kan lẹjọ lori rogbnodiyan ọrọ SARS ni oriṣiiriṣi awuyewuye ti n jẹyọ lori ọrọ naa. Ni bayii, ẹgbẹ kan to jẹ ẹgbẹ ọdọ awọn ẹya Ibo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ...

O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Arun wa lara awọn gomina ilẹ Hausa yii o Ironu wa ko jọ ara wọn. Ironu ole, ironu ka ja ohun olohun  gba lo wa ninu awọn kan ni Naijiria, bẹẹ ni ironu konikaluku jẹ iṣẹ ọwọ ẹ wa ninu awọn kan. Nigba ti eeyan ba gbọ ọrọ lẹnu awọn ti...

Aarẹ Amẹrika tuntun: Wọn tun fẹẹ ko ba wa ni Naijiria

Afi bii igba ti wọn ran ọkunrin naa sita pe ko waa daamu aye. Donald Trump, Aarẹ Amẹrika ti wọn ṣẹṣẹ fi ibo yọ ni. O ti lo ọdun mẹrin o, ọdun mẹrin mi-in lo n beere fun, ko le jẹ saa keji ti yoo lo, nitori bi gbogbo...

Kekere lohun to ṣẹlẹ yii lẹgbẹẹ eyi to n bọ- Tunde Bakare

Faith Adebọla, Eko Oludasilẹ ati adari ijọ Latter Rain Assembly tẹlẹ, to ti porukọ da si Citadel Church bayii, Pasitọ Tunde Bakare, ti sọ pe bii ọmọde meji n ṣere ni iwọde tawọn ọdọ ṣe ta ko awọn ọlọpaa SARS laipẹ yii, aifararọ ati biba dukia jẹ to ṣẹlẹ lẹyin...

Wọn fẹẹ fi rogbodiyan to ṣẹlẹ l’Ekoo din agbara ilẹ Yoruba ku ni-Akeredolu

Faith Adebọla Gomina ipinlẹ Ondo to tun jẹ alaga awọn gomina nilẹ Yoruba,  Arakunrin Ọlarotimi Akeredolu, ti sọ pe awọn kan ni wọn fẹẹ fi rogbodiyan to ṣẹlẹ niluu Eko din agbara ilẹ Yoruba ku ni. Akeredolu to gba ẹnu awọn gomina ẹgbẹ sọrọ lẹyin abẹwo ti wọn ṣe si awọn...

Gbajabiamila ṣabẹwo si Sanwo-Olu, Akiolu ati Tinubu, o ṣeleri iranlọwọ

Faith Adebọla Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, Fẹmi Gbajabiamila, ti ṣabẹwo si Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, latari rogbodiyan to ṣẹlẹ nipinlẹ naa, nibi ti ọpọ dukia ijọba ti jona guruguru. O fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa, bẹẹ lo si ba gomina atawọn eeyan ipinlẹ Eko kẹdun. Sanwo-olu mu olori...

Awọn gomina, minisita ilẹ Yoruba ṣabẹwo ibanikẹdun si Sanwo-Olu

Faith Adebọla, Eko Ṣe wọn ni alaṣọ lọrun paaka, o to nnkan apero fun gbogbo ọmọ eriwo, owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu bawọn gomina ati minisita ilẹ Yoruba ṣe ko ara wọn jọ, ti wọn si lọọ ṣabẹwo ibanikẹdun si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, latari rogbodiyan to...