Faith Adebọla Ijọba Eko ti kede pe ayiada ti ba asiko konilegbele ti wọn ti kede rẹ ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii. Lati ọjọ Aiku ọsẹ yii, awọn araalu lanfaani lati aago mẹfa aarọ di aago mẹjọ alẹ. Lati aago mẹjọ alẹ, ko sẹni to gbọdọ jade mọ. Eleyii yatọ...
Faith Adebọla, Eko Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti kede pe gbogbo ileewe nipinlẹ Eko, ati aladaani pẹlu ti ijọba ṣi wa ni titi pa, wọn ko ti i le wọle pada lati maa ba ẹkọ wọn lọ. Kọmiṣanna feto iroyin, Gbenga Ọmọtọṣọ, lo sọ eleyii di mimọ ni Sannde, ọjọ...
Aderounmu Kazeem Ọdọmọkunrin kan ni aṣita ibọn ọlọpaa ti pa danu bayii niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, lasiko tawọn janduku kan fẹẹ jo teṣan ọlọpaa to wa ni Mọkọla. Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe awọn ọdọ adugbo naa ni wọn ko gba awọn jadnuku ọhun laye nigba ti wọn kọlu teṣan ọlọpaa naa pẹlu awọn ohun ija oloro lọwọ, ti wọn si fẹẹ sọ ina si...
Aderounmu Kazeem Minista feto ọkọ ofurufu tẹlẹ lorilẹ-ede yii, Ọgbẹni Fẹmi-Fani Kayọde ti ṣapejuwe Aṣiwaju Bọla Tinubu gẹgẹ bi ika ati ọdaju eniyan, to fẹran agbara oṣelu ju ẹmi ẹda ẹgbẹ lọ. Ọkunrin ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP yii sọ pe ọ jẹ ohun to baayan ninu jẹ wi pe ọwọ yẹpẹrẹ ni Tinubu fi mu bi awọn eeyan ṣe padanu ẹmi wọn nigba tawọn ṣoja kan kọlu wọn ni too-geeti Lẹkki, l’Ekoo. O ni, “Iṣọwọ dahun ibeere nigba tawọn oniroyin...
Ọlawale Ajao, Ibadan Lẹyin rogbodiyan to ṣẹlẹ lasiko tawọn ọdọ n fẹhonu han lori SARS, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnijinnia Ṣeyi Makinde, ti pasẹ pe ki awọn ileewe wọle pada kaakiri ipinlẹ naa ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii. Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto ẹkọ ati imọ ẹrọ,lasunkanmi Ọlaleyẹ, fi...
Aderohunmu Kazeem Ninu fidio kan to farabalẹ ṣe, to ti wa nita bayii, ni ọkan lara awọn oṣere tiata Yoruba, Yẹmi My Lover, ti kọ lu awọn oṣere ẹgbẹ ẹ, paapaa awọn to ṣe oriṣiiriṣi fidio lati fi ta ko bi wọn ti ṣe pa awọn ọdọ kan nipakupa ni...
Ọlajide Kazeem Ajọ to n ri si idanwo aṣekagba ẹkọ girama, NECO, ti sun eto idanwo ọhun to n lọ lọwọ si ọjọ mi-in ọjọọre, nitori wahala to n ṣẹlẹ kaakiri orilẹ-ede yii. Ninu ọrọ ti Alukoro ajọ ọhun, Azeez Sanni, fi sita lo ti sọ pe wahala to n ṣẹlẹ...
Gomina Adegboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ pẹlu ikilọ to lagbara pe ki gbogbo ẹni to ba lọwọ ninu jiji awọn ẹru ijọba atawọn ounjẹ iranwọ COVID-19 ko tete yaa da wọn pada laarin wakati mejilelaaadọrin, iyẹn ọjọ mẹta pere, aijẹ bẹẹ, gbogbo wọn pata lo maa fimu...
Jide Kazeem Ọkan lara awọn ọmọ Aarẹ orilẹ-ede yii, Arabinrin Zahra Buhari-Indimi, ti kilọ fawọn ọmọ Naijiria pe ẹnikeni ko gbọdọ sọrọ odi si baba oun mọ, nitori oun gan-an kọ ni iṣoro Naijiria, bi ko ṣe awọn to n ko ounjẹ ti wọn pese fun COVID-19 to wa fun...
Jide Kazeem Awọn eeyan Odi, nipinlẹ Bayelsa, ti n binu si Ọbasanjọ o, ẹsun ti wọn si fi kan an ni pe ki i ṣe iru ẹ lo yẹ ko maa ba ijọba kan wi nitori to ko ṣoja kọ lu awọn araalu. Ninu atẹjade ti Igbakeji ọba ilu naa, Oloye Prenus...
Aderohunmu Kazeem Wahala nla ni awọn Fulani ti wọn ji ọmọ gbajumọ olorin Musulumi, Mumeen Damilọla, tubọ ko o si bayii pẹlu bi wọn ṣe ni ko lọọ wa ọgbọn miliọnu naira wa to ba ṣi fẹẹ ri ọmọ ẹ laaye. Ori ikaani ayelujara wasaapu lọkunrin olorin ti awọn eeyan tun...
Idowu Akinrẹmi, Ikire Ọwọ awọn oṣiṣẹ alaabo ti n tẹ awọn janduku ti wọn ji awọn nnkan ijọba ati ti ileeṣẹ alaadani kaakiri ipinlẹ naa. Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, lawọn janduku ti bẹrẹ si i lo asiko ifẹhonu han yii digunjale. Lara awọn ibi tawọn janduku ọhun ti ja, ti wọn si...
Faith Adebọla, Eko Bi adiyẹ ba da mi loogun nu, ma a si fọ ọ lẹyin lọrọ da bayii pẹlu bawọn olooṣa ṣe lọọ wa abujo ati epe kabiti kabiti le awọn to ji ọpa aṣẹ ọba Eko gbe sa lọ, ti wọn si kọ lati da a pada. Fidio kan...

0
Awọn to lọọ ji ounjẹ korona ko atawọn to dana sun dukia yoo foju bale-ẹjọ-Ijọba Eko Faith Adebọla, Eko Ojilerugba o din mọkanla (229) afurasi ọdaran lọwọ awọn agbofinro ti ba fun ọkan-o-jọkan awọn ẹsun iwa ọdaran latigba tijọba ti kede ofin konilegbele nipinlẹ Eko, gbogbo wọn pata, atawọn mi-in tọwọ...
Aderounmu Kazeem Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ti pe awọn oloṣelu ẹgbẹ ẹ lati lo iriri to n ṣẹlẹ kaakiri Naijiria bayii fi ṣeto akoso to dara siluu, kirufẹ rogbopdiyan to n ṣẹlẹ kaakiri bayii ma le waye mọ lọwọ iwaju. Ninu ọrọ to ba awọn eeyan ipinlẹ ẹ sọ laipẹ yii lo ti fidi ọrọ ọhun mulẹ wi pe asiko niyi fun gbogbo oloṣelu lati ronu wọn, ki wọn...
Aderounmu Kazeem Ẹgbẹ Afẹnifẹre ti sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa fidio kan ti awọn eeyan n pin kiri bayii, ninu eyi ti wọn ti sọ pe ki awọn ẹya Ibo, fi gbogbo ilẹ Yoruba silẹ laarin wakati mejidinlaadọta. Olori ẹgbẹ ọhun, Alagba Reuben Fasoranti, sọrọ yii niluu Akurẹ, nibi...
Aderounmu Kazeem Ọla Mọnde, ọjọ Aje, nileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Eko, ti sọ pe oun yoo bẹrẹ si ba awọn janduku ẹni afurasi ti awọn ọlọpaa mu lasiko rogbodiyan to waye l’Ekoo lọsẹ to kọja ṣẹjọ. Oriṣiriiṣi ẹsun bii ipaniyan, idaluru, ati ṣiṣe awọn dukia ijọba ati t’araalu lofo nileeṣẹ to...
Faith Adebọla, Eko Gomina ipinlẹ Eko nigba kan ati aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, ti fi ẹdun ọkan rẹ han si bi awọn janduku ṣe ba ọpọ dukia ijọba ati ti aladaani jẹ kaakiri ipinlẹ Eko, o ni iṣẹlẹ ọhun ṣe oun laaanu gidigidi, ati pe iroyin irọ...
Stephen Ajagbe, ilọrin Bi a ti ṣe kọ iroyin yii, gbogbo agbegbe ile itaja nla Shoprite to wa lọna Fate, niluu Ilọrin, ti di akọlu-kọgba, nitori bawọn eeyan ti wọn fura si pe wọn jẹ janduku ṣe ya bo ibẹ, ti wọn si n ji awọn ọja wọn ko. Ọpọlọpọ eeyan,...
Stephen Ajagbe, Ilorin Bii igba ti wọn ba wa loju ogun ni ọrọ ri lana-an, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni olu ileeṣẹ ajọ aṣọbode niluu Ilọrin, nigba tawọn janduku kan to waa kọ lu ọfiisi naa gbena woju ara wọn pẹlu awọn ọmọ ileeṣẹ ologun. AKEDE AGBAYE gbọ pe awọn...