Kazeem Aderohunmu O jọ pe pupọ ninu awọn araalu ni ko fẹẹ duro de ijọba tabi oloṣelu kankan mọ lori ohun iranwọ ti wọn maa n ṣe fun wọn, niṣe ni wọn lọọ n fọle, ti wọn si n fọwọ ara wọn ko ohun ti wọn ba fẹ.Idi ni pe...
Idowu Akinrẹmi, Ikire Gomina ipinlẹ Ọsun, Isiaq Gboyega Oyetọla tun ti kede konilegbele miiran lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, ti i ṣe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, yii kaakiri ipinlẹ Ọṣun. Gomina ni oun gbe igbesẹ naa lẹyin ipade pajawiri lori eto aabo ipinlẹ naa. O ni igbesẹ yii waye latari bi...
Stephen Ajagbe, Ilorin Alẹ ọjọ Ẹti, Furaide, niroyin gba igboro pe awọn janduku kan kọ lu ileeṣẹ iwe iroyin National Pilot to wa lọna Asa Dam, niluu Ilọrin, ti wọn si ba awọn nnkan jẹ nibẹ. ALAROYE gbọ pe ori lo ko Olootu agba iwe iroyin naa, Billy Adedamọla, atawọn oṣiṣẹ...
Aderounmu Kazeem Ninu idaamu nla ni gbajumọ olorin ẹsin Islam nni, Mummen Damilọla, wa bayii pẹlu bi awọn janduku kan ṣe kọlu awọn ẹbi ẹ n’Ilọrin. Wọn ni aṣalẹ ana ni iṣẹlẹ ọhun waye ni Gaa Saka, lẹgbẹẹ Adewọle niluu Ilọrin nipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti pa iyawo aburo ẹ, ki wọn too tun gbe ọmọ ẹ, Abdul-Basit Damilọla, to jẹ ọmọleewe Kwara Poli lọ. Awọn...
Kazeem Aderohunmu Nile awo kan ti wọn pe ni Tẹmpili Ọsẹ meji niluu Ibadan lawọn ẹlẹsin ibilẹ ti ṣepade laipẹ yii, ohun ti wọn si sọ ni pe, Aarẹ Muhammed Buhari gbọdọ ṣe pẹlẹ, ko yee fọrọ ẹsin ati iwa ẹlẹyamẹya dari Naijiria. Wọn ni bo tilẹ jẹ pe latigba ti...
O tan! Awọn alawo n binu si Buhari Nile awo kan ti wọn pe ni Tẹmpili Ọsẹ meji niluu Ibadan lawọn ẹlẹsin ibilẹ ti ṣepade laipẹ yii, ohun ti wọn si sọ ni pe Aarẹ Muhammed Buhari gbọdọ ṣe pẹlẹ, ko yee fọrọ ẹsin ati iwa ẹlẹyamẹya dari Naijiria. Wọn ni bo...
Florence Babaṣọla, Oṣogbo Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ti awọn araalu ti n ko ẹru Corvid-19 niluu Ẹdẹ lawọn janduku kan ti dara pọ mọ wọn. Nidaaji ọjọ Abamẹta, Satide opin ọsẹ yii, ileeṣẹ Alhaji Tunde Badmus, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Tuns Farm ni wọn kọkọ lọ loju ọna Oṣogbo...
Aderounmu Kazeem Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, oluranlọwọ fun Aarẹ Muhammed Buhari, lo sọrọ kan sinu iwe iroyin laipẹ yii, ohun to si sọ ni pe, ti Naijiria, ba fi le ku, ikorira ti awọn eeyan ni si i ati sira wọn gan an lo pa a. Wahala nla to n ṣelẹ lọwọ...
Aderounmu Kazeem Lati fopin si rogbodiyan to n ṣẹlẹ lawọn ibi kan nilẹ Yoruba, lori bi wọn ti ṣe n jo ile, ti wọn n kọlu awọn teṣan ọlọpaa kiri, awọn aṣoju-ṣofin ti sọ pe, iru iwa bẹẹ gbọdọ dopin. Awọn asoju-sofin kan ti wọn je ọmọ Yoruba, eyi ti Ọnarebu...
Jide Alabi O jọ pe ọna kan tawọn eeyan tun gba fi n fẹhonu han bayii lai jo ile tabi ba dukia kankan jẹ ni bi wọn ti ṣe n lọ si gbogbo ibi ti ijọba ko ounjẹ to yẹ ki wọn fun wọn lasiko isemọle ajakalẹ arun koronafairọọsi pamọ...
Aderounmu Kazeem Igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Ọbafẹmi Hamzat, ti ṣeleri fawọn eeyan ipinlẹ naa, paapaa awọn ti wọn padanu dukia wọn atawọn ti wọn ja sọọbu wọn wi pe ijọba yoo ṣeto iranwọ fun wọn. Lana-an ọjọ Ẹti naa lo sọ ọ lori ayelujara abẹyẹfo ẹ, (Twitter), bẹẹ lo fi ikanni...
Aderounmu Kazeem Lati fopin si bi awọn eeyan orilẹ-ede yii atawọn ilẹ okeere ṣe n binu si Buhari nitori ti ko sọ ohunkohun nipa wahala to ṣẹlẹ ni too-geeti Lẹki, l’Ekoo, ọkan ninu awọn minisita ẹ ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ ọhun bayii. Ọgbẹni Sunday Dare, ẹni ti ṣe minisita...
Kazeem Aderohunmu Nitori rogbodiyan to ṣẹlẹ ni Lẹkki, nibi ti awọn ọlọpaa ti dana ibọn bo awọn ọdọ to n ṣewọde, ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Ibironkẹ Ojo ti gbogbo eeyan mọ si Ronkẹ Oṣodi, ti kabaamọ pe oun polongo ibo fun awọn oloṣelu ilẹ wa. Oṣere naa da...
Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ Gomina Rotimi Akeredolu ti gbẹsẹ kuro lori ofin konilegbele oniwakati mẹrinlelogun tijọba kede rẹ latari rogbodiyan to suyọ lori iwọde SARS ti wọn ṣe lawọn apa ibi kan nipinlẹ Ondo. Ikede yii waye ninu atẹjade ti gomina fi sita lati ọwọ Kọmisanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ondo,...
Faith Adebọla Gomina ipinlẹ Eko, Babajide ti gba awọn awakọ atawọn araalu nimọran lati ṣe jẹjẹ loju popo nitori oriṣiriṣii nnkan tawọn janduku ti ju si oju ọna. O ni bi awọn eeyan ko ba nidii lati jade, ki wọn ma wulẹ bọ sita rara nitori oriṣiriṣii nnkan bii...
Kaakiri ipinlẹ ni awọn araalu ti n wa ile ẹru ti ijọba ko ounjẹ korona to yẹ ki wọn ti pin fun araalu, ṣugbọn ti wọn ko pin in bayii. Erongba wọn ni lati lọ sibe, ki wọn si pin ounjẹ naa laarin ara wa. Ni bayii, ipinlẹ bii mẹta...
Faith Adebọla, Eko Lati Satide, ọjọ Abamẹta, awọn eeyan ipinlẹ le maa jade lati aago mẹjọ aarọ si aago mẹfa alẹ. Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lo kede ọrọ naa lasiko to n ba gbogbo araalu sọrọ lori bo ṣe dẹ ikede konilegbele to ṣe nipinlẹ Eko. Bẹẹ lo kilọ...
Florence Babaṣọla, Oṣogbo Gbogbo ounjẹ gbigbẹ tijọba apapọ ko pamọ si agbegbe Ọṣun Ankara, ni Irojo, niluu Ileṣa, lawọn araalu tinu n bi ti ko tan bayii. Silo yii ni wọn kọ lasiko iṣejọba Aarẹ Goodluck Jonathan. O wa kaakiri orileede yii. Ṣe nijọba apapọ maa n ko ounjẹ  sibẹ lasiko...
Stephen Ajagbe, Ilọrin Bi ki i ba ṣe tawọn agbofinro ti wọn tete da awọn eeyan to n gbiyanju lati wọ ibudo tijọba ipinlẹ Kwara ko awọn ohun iranwọ si lọjọ Ẹti, Furaidee, niṣe ni  wọn iba palẹ gbogbo ẹ mọ. Ọpọlọpọ araalu ni wọn ya bo ibudo naa to wa...
Kazeem Aderohunmu  Pẹlu ibanujẹ lawọn oṣere tiata Yoruba fi kede iku ọkan pataki ninu wọn to ku lọjọ Ẹti, Furaidee. Ọkanninu awọn oṣere naa, Kunle Afod, lo kọkọ gbe e sori ẹrọ agbọrọkaye, Instgiraamu, rẹ, nibi to kọ ̀ọ si Arabinrin Ẹniọla Kuburat naa ti dagbere faye pe o digbooṣe. Ohun ti Kunle...